12 Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi.
13 Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.”
14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu láti ṣe yín ní ibi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, tí n kò sì yí ìpinnu mi pada,
15 bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù.
16 Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá.
17 Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”
18 OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní,