15 bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù.
16 Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá.
17 Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”
18 OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní,
19 “Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia.
20 “Ọ̀pọ̀ eniyan yóo ti oríṣìíríṣìí ìlú wá sí Jerusalẹmu,
21 àwọn ará ìlú kan yóo máa rọ àwọn ará ìlú mìíràn pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ kíákíá láti wá ojurere OLUWA, ati láti sin OLUWA àwọn ọmọ ogun; ibẹ̀ ni mò ń lọ báyìí.’