1 OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli.
2 Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
3 Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba.
4 Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun.
5 Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro.