14 Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó;ẹ̀yin ọmọ Israẹli!Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi,ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!
15 OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò,ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ.OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín;ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́.
16 Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé:“Ẹ má ṣe fòyà;ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù.
17 OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;yóo láyọ̀ nítorí yín,yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè
18 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”OLUWA ní:“N óo mú ibi kúrò lórí yín,kí ojú má baà tì yín.
19 N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,n óo gba àwọn arọ là,n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògogbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.
20 N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà,nígbà tí mo bá ko yín jọ tán:n óo sọ yín di eniyan patakiati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé,nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín,Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”