7 Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada.
8 Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.
9 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.
10 Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi.
11 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan.
12 Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí.
13 Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run.