Galatia 2 BM

Àwọn Aposteli yòókù Gba Paulu Bí Aposteli

1 Lẹ́yìn ọdún mẹrinla ni mo tó tún gòkè lọ sí Jerusalẹmu pẹlu Banaba. Mo mú Titu lọ́wọ́ pẹlu.

2 Ọlọrun ni ó fihàn mí lójúran ni mo fi lọ. Mo wá ṣe àlàyé níwájú àwọn aṣaaju nípa ìyìn rere tí mò ń waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Níkọ̀kọ̀ ni a sọ̀rọ̀ kí gbogbo iré-ìje tí mò ń sá ati èyí tí mo ti sá má baà jẹ́ lásán.

3 Kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kí á kọ Titu tí ó wà pẹlu mi nílà nítorí pé ọmọ ẹ̀yà Giriki ni.

4 Àwọn tí ó gbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọlà Titu jáde ni àwọn arakunrin èké tí wọ́n yọ́ wá wo òmìnira wa tí a ní ninu Kristi Jesu, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú òfin.

5 Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín.

6 Ṣugbọn àwọn tí wọn ń pè ní aṣaaju ninu wọn kò kọ́ mi ní ohun titun kan. Ohun tí ó mú kí n sọ̀rọ̀ báyìí ni pé kò sí ohun tí ó kàn mí ninu ọ̀rọ̀ a-jẹ́-aṣaaju tabi a-kò-jẹ́-aṣaaju. Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.

7 Ṣugbọn wọ́n wòye pé a ti fi iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà fún mi ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fún Peteru ní iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn tí ó kọlà.

8 Nítorí ẹni tí ó fún Peteru ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí wọ́n kọlà ni ó fún mi ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

9 Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà.

10 Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe.

Paulu Bá Peteru Wí ní Antioku

11 Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí.

12 Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà.

13 Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn!

14 Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”

Igbagbọ Ni Ọ̀nà Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan

15 Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀,

16 mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin.

17 Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o!

18 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀.

19 Nítorí nípa òfin, mo ti kú sinu òfin kí n lè wà láàyè lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti kàn mí mọ́ agbelebu pẹlu Kristi.

20 Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi.

21 Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni.

orí

1 2 3 4 5 6