22 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira.
23 Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun.
24 Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari.
25 Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀.
26 Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa.
27 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí.Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”
28 Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín.