6 Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́.
7 Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun.
8 Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun.
9 Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn?
10 Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún!
11 Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!
12 Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá.