1 Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò.
2 Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ.
3 Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ.
4 Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn.
5 Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀.
6 Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀.
7 Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká.