11 Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
12 Ẹni tí ó bá fi ara da ìdánwò kú oríire, nítorí nígbà tí ó bá yege tán, yóo gba adé ìyè tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.
13 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò.
14 Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò.
15 Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú.
16 Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ.
17 Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.