11 Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa.
12 Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́.
13 Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá wà ninu ìyọnu, kí olúwarẹ̀ gbadura. Bí inú ẹnikẹ́ni ninu yín bá dùn, kí olúwarẹ̀ máa kọ orin ìyìn.
14 Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ń ṣàìsàn, kí ó pe àwọn àgbà ìjọ jọ, kí wọ́n gbadura fún un, kí wọ́n fi òróró pa á lára ní orúkọ Oluwa.
15 Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í.
16 Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i.
17 Eniyan ẹlẹ́ran-ara bí àwa ni Elija. Ó fi tọkàntọkàn gbadura pé kí òjò má rọ̀. Òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún odidi ọdún mẹta ati oṣù mẹfa.