7 Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn.
8 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé.
9 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà.
10 Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú.
11 Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa.
12 Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́.
13 Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá wà ninu ìyọnu, kí olúwarẹ̀ gbadura. Bí inú ẹnikẹ́ni ninu yín bá dùn, kí olúwarẹ̀ máa kọ orin ìyìn.