43 Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”
44 Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi.
45 Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”
46 Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?”Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”
47 Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”
48 Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?”Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.”
49 Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.”