Johanu 13 BM

Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀

1 Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.

2 Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

3 Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ.

4 Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí,

5 ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀.

6 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?”

7 Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.”

8 Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!”Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”

9 Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”

10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”

11 Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.”

12 Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín?

13 Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

14 Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín.

15 Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe.

16 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ.

17 Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.

18 “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’

19 Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.

20 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”

Jesu Sọ Ẹni Tí Yóo fi Òun fún Àwọn Ọ̀tá

21 Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”

22 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú.

23 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.

24 Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.

25 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”

26 Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu.

27 Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.”

28 Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un.

29 Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”

30 Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.

Òfin Titun

31 Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan.

32 Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ.

33 Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.

34 Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.

35 Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóo Sẹ́ Òun

36 Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?”Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.”

37 Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.”

38 Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21