31 Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú.
32 Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”
33 Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.”
34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’
35 Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run,
36 kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?
37 Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.