19 Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!”
20 Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà.
21 Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”
22 Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.
23 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo.
24 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá.
25 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun.