29 Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.”
30 Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín.
31 Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde.
32 Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.”
33 Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú.
34 Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”
35 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.