36 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.”Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.
37 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.
38 Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé,“Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́?Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?”
39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé,
40 “Ojú wọn ti fọ́,ọkàn wọn sì ti le;kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,kí òye má baà yé wọn.Kí wọn má baà yipada,kí n má baà wò wọ́n sàn.”
41 Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.
42 Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ;