8 Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
9 Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi.
10 Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀.
11 “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
12 Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.
13 Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
14 Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín.