14 Yóo fi ògo mi hàn nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo ti gba àwọn ohun tí yóo sọ fun yín.
15 Tèmi ni ohun gbogbo tí Baba ní. Ìdí nìyí ti mo ṣe sọ pé ohun tí ó bá gbà láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo sọ fun yín.
16 “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.”
17 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ”
18 Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.”
19 Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’
20 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀.