4 Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín.“N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín.
5 Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’
6 Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín.
7 Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.
8 Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.
9 Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́.
10 Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́.