4 Èmi ti fi ògo fún ọ ninu ayé, mo ti parí iṣẹ́ tí o fún mi ṣe.
5 Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi.
6 “Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.
7 Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá.
8 Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.
9 “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n.
10 Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ.