8 Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.
9 “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n.
10 Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ.
11 Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan.
12 Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.
13 Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn.
14 Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé.