2 Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
3 Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà.
4 Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”
5 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.
6 Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.
7 Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”
8 Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”