7 Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.
8 Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?”
9 Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.”Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.”
10 Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”
11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”
12 Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?”Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”
13 Àwọn kan bá mú ọkunrin tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi.