6 Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́.
7 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa.
8 Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí.
9 Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí.
10 A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun.
11-12 Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀.
13 Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀.