1 Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.
2 Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé.
3 Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.
4 Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo.
5 Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà.
6 Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀.
7 Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi.
8 Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú.
9 Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀,
10 tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun.
11 Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo.
12 Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀.
13 Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín.
14 Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé.
15 Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́.
16 Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.
17 Ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni tabi pé ẹ̀ ń ṣe nǹkankan ni, ẹ máa ṣe é ní orúkọ Oluwa Jesu. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nípasẹ̀ rẹ̀.
18 Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí onigbagbọ máa ṣe.
19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn.
20 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo, nítorí ohun tí ó wu Oluwa nìyí.
21 Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò mọ́ àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn.
22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn olówó yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Kí ó má jẹ́ pé nígbà tí wọn bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́, bí ìgbà tí ó jẹ́ pé eniyan ni ẹ̀ ń fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Ṣugbọn ẹ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, ní ìbẹ̀rù Oluwa.
23 Ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn, bí ẹni pé Oluwa ni ẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe fún eniyan,
24 níwọ̀n ìgbà tí ẹ mọ̀ pé ẹ óo rí ogún gbà gẹ́gẹ́ bí èrè láti ọ̀dọ̀ Oluwa. Oluwa Kristi ni ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ ẹrú fún.
25 Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣe àìdára, yóo gba èrè àìdára. Kò ní sí ojuṣaaju.