13 Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
14 Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu.
15 Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu.
16 Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi.
17 Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki.
18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀;
19 kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́.