1 Ẹ̀yin ọ̀gá, ohun tí ó dára ati ohun tí ó yẹ ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Kí ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run.
2 Ẹ tẹra mọ́ adura gbígbà. Ẹ máa fi ọkàn bá adura yín lọ. Kí ẹ sì máa dúpẹ́.
3 Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n.
4 Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ.
5 Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ.
6 Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn.