12 Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun.
13 Nítorí pé mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ti ṣiṣẹ́ pupọ fun yín ati fún àwọn tí ó wà ní Laodikia ati ní Hierapoli.
14 Luku, àyànfẹ́ oníṣègùn ati Demasi ki yín.
15 Ẹ kí àwọn arakunrin tí ó wà ní Laodikia. Ẹ kí Nimfa ati ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.
16 Nígbà tí ẹ bá ti ka ìwé yìí tán, kí ẹ rí i pé ìjọ tí ó wà ní Laodikia kà á pẹlu. Kí ẹ̀yin náà sì ka ìwé tí a kọ sí àwọn ará Laodikia.
17 Ẹ sọ fún Akipu pé kí ó má jáfara nípa iṣẹ́ tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Oluwa, kí ó ṣe é parí.
18 Ìkíni tí èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ nìyí. Ẹ ranti pé ninu ẹ̀wọ̀n ni mo wà.Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹlu yín.