3 Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n.
4 Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ.
5 Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ.
6 Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn.
7 Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa.
8 Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀.
9 Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín.