9 Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín.
10 Arisitakọsi, ẹlẹ́wọ̀n, ẹlẹgbẹ́ mi ki yín, ati Maku, ìbátan Banaba. Ẹ ti rí ìwé gbà nípa rẹ̀. Tí ó bá dé ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀.
11 Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi.
12 Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun.
13 Nítorí pé mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ti ṣiṣẹ́ pupọ fun yín ati fún àwọn tí ó wà ní Laodikia ati ní Hierapoli.
14 Luku, àyànfẹ́ oníṣègùn ati Demasi ki yín.
15 Ẹ kí àwọn arakunrin tí ó wà ní Laodikia. Ẹ kí Nimfa ati ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.