Peteru Keji 3 BM

Ìlérí Pé Oluwa Yóo tún Pada Wá

1 Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀.

2 Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín.

3 Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.

4 Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!”

5 Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun.

6 Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run.

7 Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run.

8 Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan.

9 Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.

10 Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.

11 Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn,

12 kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná.

13 Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, à ń dúró de àwọn ọ̀run titun ati ayé titun níbi tí òdodo yóo máa wà.

14 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun.

15 Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un.

16 Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.

17 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.

18 Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin.

orí

1 2 3