1 Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.
2 Ẹ ṣe bí ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí òùngbẹ wàrà gidi ti ẹ̀mí ń gbẹ, kí ó lè mu yín dàgbà fún ìgbàlà.
3 Ó ṣá ti hàn si yín pé olóore ni Oluwa.
4 Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀.
5 Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi.
6 Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé,“Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni,àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye.Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”
7 Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí,“Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pataki igun ilé.”