Peteru Kinni 1 BM

1 Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia.

2 Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.

Ìrètí tí Ó Wà Láàyè

3 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú.

4 Ó fún wa ni ogún ainipẹkun, ogún tí kò lè díbàjẹ́, tí kò lè ṣá, tí a ti fi pamọ́ fun yín ní ọ̀run.

5 Ẹ̀yin ni a ti dáàbò bò nípa agbára Ọlọrun nípa igbagbọ sí ìgbàlà tí a ti ṣe ètò láti fihàn ní ọjọ́ ìkẹyìn.

6 Ẹ máa yọ̀ nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún àkókò díẹ̀, ẹ níláti ní ìdààmú nípa oríṣìíríṣìí ìdánwò.

7 Wúrà níláti kọjá ninu iná, bẹ́ẹ̀ sì ni ó pẹ́ ni, ó yá ni, yóo ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a níláti dán igbagbọ yín tí ó ní iye lórí ju wúrà lọ wò. Irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ yóo gba ìyìn, ògo, ati ọlá nígbà tí Jesu Kristi bá dé.

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i, sibẹ ẹ fẹ́ràn rẹ̀. Ẹ kò rí i sójú nisinsinyii, sibẹ ẹ gbà á gbọ́, ẹ sì ń yọ ayọ̀ tí ẹnu kò lè sọ, ayọ̀ tí ó lógo,

9 nítorí pé ẹ jèrè igbagbọ yín nípa ìgbàlà ọkàn yín.

10 Àwọn wolii tí wọ́n ṣe ìkéde oore-ọ̀fẹ́ tún fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ìgbàlà yìí.

11 Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀.

12 Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.

Ìpè sí Ìgbé-Ayé Mímọ́

13 Nítorí náà, ẹ ṣe ọkàn yìn gírí. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́. Ẹ máa retí oore-ọ̀fẹ́ tí yóo jẹ́ tiyín nígbà tí Jesu Kristi bá tún dé.

14 Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ń gbọ́ràn, ẹ má gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni.

15 Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín.

16 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Ọlọrun ní, “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí èmi náà jẹ́ mímọ́.”

17 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń pe Ọlọrun ní Baba tí kì í ṣe ojuṣaaju, tí ó jẹ́ pé bí iṣẹ́ olukuluku bá ti rí ní ó fi ń ṣe ìdájọ́, ẹ máa fi ìbẹ̀rù gbé ìgbé-ayé yín ní ìwọ̀nba àkókò tí ẹ ní.

18 Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí ó lè bàjẹ́, bíi fadaka ati wúrà, ni a fi rà yín pada kúrò ninu ìgbé-ayé asán tí ẹ jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19 Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n.

20 Kí á tó dá ayé ni a ti yan Kristi fún iṣẹ́ yìí. Ṣugbọn ní àkókò ìkẹyìn yìí ni ó tó fi ara hàn nítorí tiyín.

21 Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun.

22 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.

23 A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí.

24 Nítorí,“Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko,gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó.Koríko a máa gbẹ,òdòdó a máa rẹ̀,

25 ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.”Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín.

orí

1 2 3 4 5