6 Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.
7 Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín.
8 Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.
9 Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.
10 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú,tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára,ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánupẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ,kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
11 Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú,kí ó máa hu ìwà rere.Ó níláti máa wá alaafia,kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo,ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.Ṣugbọn ojú Oluwa kan síàwọn tí ó ń ṣe burúkú.”