11 Òun ni agbára wà fún laelae. Amin.
12 Silifanu ni ó bá mi kọ ìwé kúkúrú yìí si yín. Mo ka Silifanu yìí sí arakunrin tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹ dúró lórí ohun tí mo kọ.
13 Ìjọ tí Ọlọrun yàn, ẹlẹgbẹ́ yín tí ó wà ní Babiloni ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maku, ọmọ mi.
14 Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.Kí alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ti Kristi.