5 Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí,“Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga,ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀.
7 Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún.
8 Ẹ ṣọ́ra. Ẹ dira yín gírí, Èṣù tíí ṣe ọ̀tá yín, ń rìn kiri bíi kinniun tí ń bú ramúramù, ó ń wá ẹni tí yóo pa jẹ.
9 Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.
10 Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀.
11 Òun ni agbára wà fún laelae. Amin.