3 Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà,
4 kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ.
5 Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn.
6 Àwọn mìíràn ti kùnà nípa irú èyí; wọ́n ti yipada sí ọ̀rọ̀ asán.
7 Wọn á fẹ́ máa kọ́ni ní òfin, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ohun tí wọ́n sì ń sọ pẹlu ìdánilójú kò yé wọn.
8 A mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun tí ó dára bí a bá lò ó bí ó ti tọ́.
9 A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn,