Timoti Kinni 5 BM

Iṣẹ́ sí Àwọn tí ó Gbàgbọ́

1 Má máa fi ohùn líle bá àwọn àgbàlagbà wí, ṣugbọn máa gbà wọ́n níyànjú bíi baba rẹ. Máa ṣe sí àwọn ọdọmọkunrin bí ẹ̀gbọ́n ati àbúrò rẹ.

2 Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo.

3 Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan.

4 Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun.

5 Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru.

6 Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé.

7 Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn.

8 Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ.

9 Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan,

10 tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo.

11 Ṣọ́ra nípa kíkọ orúkọ àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sílẹ̀, nítorí nígbà tí ara wọn bá gbóná, wọn yóo kọ ètò ti Kristi sílẹ̀, wọn yóo fẹ́ tún lọ́kọ.

12 Wọn yóo wá gba ẹ̀bi nítorí wọ́n ti kọ ẹ̀jẹ́ wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀.

13 Ati pé nígbà tí wọn bá ń tọ ojúlé kiri, wọ́n ń kọ́ láti ṣe ìmẹ́lẹ́. Kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nìkan, wọn a máa di olófòófó ati alátojúbọ̀ ọ̀ràn-ọlọ́ràn, wọn a sì máa sọ ohun tí kò yẹ.

14 Nítorí náà mo fẹ́ kí àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tún lọ́kọ, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n ní ilé tiwọn. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ọ̀tá láti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

15 Nítorí àwọn mìíràn ti yipada, wọ́n ti ń tẹ̀lé Satani.

16 Bí onigbagbọ obinrin kan bá ní àwọn opó ninu ẹbí rẹ̀, òun ni ó níláti ṣe ìtọ́jú wọn. Kò níláti di ẹrù wọn lé ìjọ Ọlọrun lórí, kí ìjọ lè mójútó àwọn tí wọ́n jẹ́ opó gidi.

17 Ó yẹ kí àwọn àgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ aṣiwaju dáradára gba ìdálọ́lá ọ̀nà meji, pataki jùlọ àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ oníwàásù ati olùkọ́ni.

18 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Má ṣe dí mààlúù tí ó ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ati pé, “Owó oṣù òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.”

19 Bí ẹnìkan bá fi ẹ̀sùn kan àgbàlagbà, má ṣe kà á sí àfi tí ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta bá wà.

20 Bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba, kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù.

21 Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju.

22 Má fi ìwàǹwára gbé ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni lórí láti fi jẹ oyè ninu ìjọ, má sì di alábàápín ninu ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ mọ́.

23 Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo.

24 Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde.

25 Bákan náà ni, iṣẹ́ rere a máa hàn sí gbogbo eniyan. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò ṣe é bò mọ́lẹ̀ títí.

orí

1 2 3 4 5 6