3 Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó.
4 Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
5 Nítorí ẹni tí kò káwọ́ ilé ara rẹ̀, báwo ni ó ṣe lè mójútó ìjọ Ọlọrun?
6 Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani.
7 Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un.
8 Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan.
9 Wọ́n níláti di ohun ìjìnlẹ̀ igbagbọ mú pẹlu ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́.