6 Bí o bá ń fi irú ọ̀rọ̀ báyìí siwaju àwọn arakunrin, ìwọ yóo jẹ́ òjíṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a tọ́ dàgbà ninu ọ̀rọ̀ igbagbọ ati ẹ̀kọ́ rere tí ò ń tẹ̀lé.
7 Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun.
8 Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀.
9 Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn.
10 Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.
11 Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan.
12 Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé.