1 Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí.
2 Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà!
3 Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ.
4 Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade.
5 Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin.
6 Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn.