1 ADURA Habakuku woli lara Sigionoti.
2 Oluwa, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, ẹ̀ru si bà mi: Oluwa, mu iṣẹ rẹ sọji lãrin ọdun, lãrin ọdun sọ wọn di mimọ̀; ni ibinu ranti ãnu.
3 Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀.
4 Didán rẹ̀ si dabi imọlẹ; itanṣan nti iha rẹ̀ wá: nibẹ̀ si ni ipamọ agbara rẹ̀ wà.
5 Ajàkalẹ arùn nlọ niwaju rẹ̀, ati okunrun njade lati ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ.
6 O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni.
7 Mo ri agọ Kuṣani labẹ ipọnju: awọn aṣọ-ikele ilẹ̀ Midiani si warìri.
8 Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ?
9 A ṣi ọrun rẹ̀ silẹ patapata, gẹgẹ bi ibura awọn ẹ̀ya, ani ọ̀rọ rẹ. Iwọ ti fi odò là ilẹ aiye.
10 Awọn oke-nla ri ọ, nwọn si warìri: akúnya omi kọja lọ: ibú fọ̀ ohùn rẹ̀, o si gbe ọwọ́ rẹ̀ si oke.
11 Õrùn ati oṣupa duro jẹ ni ibùgbe wọn: ni imọlẹ ọfà rẹ ni nwọn lọ, ati ni didán ọ̀kọ rẹ ti nkọ màna.
12 Ni irúnu ni iwọ rìn ilẹ na ja, ni ibinu ni iwọ ti tẹ̀ awọn orilẹ-ede rẹ́.
13 Iwọ jade lọ fun igbàla awọn enia rẹ, fun igbàla ẹni atororosi rẹ; iwọ ti ṣá awọn olori kuro ninu ile awọn enia buburu, ni fifi ipinlẹ hàn titi de ọrùn.
14 Iwọ ti fi ọ̀pa rẹ̀ lu awọn olori iletò rẹ̀ já: nwọn rọ́ jade bi ãjà lati tu mi ka: ayọ̀ wọn ni bi ati jẹ talakà run nikọ̀kọ.
15 Iwọ fi awọn ẹṣin rẹ rìn okun ja, okìti omi nla.
16 Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro.
17 Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ:
18 Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi.
19 Oluwa Ọlọrun ni agbara mi, on o si ṣe ẹsẹ̀ mi bi ẹsẹ̀ agbọ̀nrin, lori ibi giga mi ni yio si mu mi rìn. Si olori akọrin lara ohun-ọnà orin olokùn mi.