7 Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn?
8 Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
9 Egbe ni fun ẹniti njẹ erè ijẹkujẹ si ile rẹ̀, ki o lè ba gbe itẹ́ rẹ̀ ka ibi giga, ki a lè ba gbà a silẹ kuro lọwọ ibi!
10 Iwọ ti gbìmọ itìju si ile rẹ, nipa kike enia pupọ̀ kuro, o si ti ṣẹ̀ si ọkàn rẹ.
11 Nitoriti okuta yio kigbe lati inu ogiri wá, ati igi-idábu lati inu òpo wá yio si da a lohùn.
12 Egbe ni fun ẹniti o fi ẹjẹ̀ kọ ilu, ti o si fi aiṣedede tẹ̀ ilu nla do.
13 Kiyesi i, ti Oluwa awọn ọmọ-ogun kọ́ pe, ki awọn enia na ma ṣe lãla fun iná, ati ki awọn enia na si ma ṣe ara wọn li ãrẹ̀ fun asan?