10 Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn.
11 Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a?
12 Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọ̀fọ.
13 Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu.
14 Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin?
15 Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ yà ãwẹ̀ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ ti o ni irònu.
16 Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀.