4 Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ.
5 Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra.
6 Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé.
7 Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona.
8 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe?
9 On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ.
10 Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn.