Jon 4 YCE

Ibinu Jona ati Àánú Ọlọrun

1 ṢUGBỌN o bà Jona ninu jẹ́ gidigidi, o si binu pupọ̀.

2 O si gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ ọ, Oluwa, ọ̀rọ mi kọ yi nigbati mo wà ni ilẹ mi? nitorina ni mo ṣe salọ si Tarṣiṣi ni iṣaju: nitori emi mọ̀ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na.

3 Njẹ nitorina, Oluwa, emi bẹ ọ, gbà ẹmi mi kuro lọwọ mi nitori o sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè.

4 Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ ha ṣe rere lati binu?

5 Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na.

6 Oluwa Ọlọrun si pese itakùn kan, o si ṣe e ki o goke wá sori Jona; ki o le ṣiji bò o lori; lati gbà a kuro ninu ibinujẹ rẹ̀. Jona si yọ ayọ̀ nla nitori itakùn na.

7 Ṣugbọn Ọlọrun pese kokorò kan nigbati ilẹ mọ́ ni ijọ keji, o si jẹ itakùn na, o si rọ.

8 O si ṣe, nigbati õrun là, Ọlọrun si pese ẹfufu gbigbona ti ila-õrùn; õrùn si pa Jona lori, tobẹ̃ ti o rẹ̀ ẹ, o si fẹ́ ninu ara rẹ̀ lati kú, o si wipe, O sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè lọ.

9 Ọlọrun si wi fun Jona pe, O ha tọ́ fun ọ lati binu nitori itakùn na? on si wipe, O tọ́ fun mi lati binu titi de ikú.

10 Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ kẹdùn itakùn na nitori eyiti iwọ kò ṣiṣẹ, bẹ̃li iwọ kò mu u dagbà; ti o hù jade li oru kan ti o si kú li oru kan.

11 Ki emi ki o má si da Ninefe si, ilu nla nì, ninu eyiti jù ọ̀kẹ-mẹfa enia wà ti kò le mọ̀ ọtun mọ̀ osì ninu ọwọ́ wọn, ati ọ̀pọlọpọ ohun-ọsìn?

orí

1 2 3 4