1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe,
2 Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ.
3 Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta.
4 Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo.
5 Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn.
6 Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru.