9 Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun.
10 Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ.
11 Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin?
12 Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin;
13 Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi.
14 Nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si tun sọkun: Orpa si fi ẹnu kò iya-ọkọ rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn Rutu fàmọ́ ọ.
15 On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ.